I. Kor 6:9-10
I. Kor 6:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
I. Kor 6:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́, Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun.
I. Kor 6:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin; àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun.