Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

I. A. Ọba 8:56YBCV(Bibeli Mimọ)

Ibukún ni fun Oluwa ti o ti fi isimi fun Israeli enia rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ṣe ileri: kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo ileri rere rẹ̀ ti o ti ṣe lati ọwọ Mose, iranṣẹ rẹ̀ wá.

I. A. Ọba 8:56BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ìbùkún ni fún OLúWA tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.

I. A. Ọba 8:56YCE(Yoruba Bible)

“Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.