II. Kor 5:14-15
II. Kor 5:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú: O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde.
II. Kor 5:14-15 Yoruba Bible (YCE)
nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú. Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde.
II. Kor 5:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.