II. Sam 11:2-3
II. Sam 11:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò. Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti?
II. Sam 11:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Dafidi jí lójú oorun, ó gun orí òrùlé ààfin rẹ̀. Bí ó ti ń rìn káàkiri níbẹ̀, ó rí obinrin kan tí ń wẹ̀, obinrin náà jẹ́ arẹwà gidigidi. Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ, láti wádìí aya ẹni tí obinrin náà í ṣe. Ẹnìkan sì sọ fún un pé Batiṣeba ọmọ Eliamu ni, aya Uraya, ará Hiti.
II. Sam 11:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò. Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti.