Iṣe Apo 7:34 - Compare All Versions

Iṣe Apo 7:34 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti.

Iṣe Apo 7:34 YCE (Yoruba Bible)

Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’

Iṣe Apo 7:34 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ní rí rí, mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’