Kol 2:8 - Compare All Versions

Kol 2:8 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi.

Kol 2:8 YCE (Yoruba Bible)

Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi.

Kol 2:8 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.