Dan 3:16-18
Dan 3:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dahùn, nwọn si wi fun ọba pe, Nebukadnessari, kò tọ si wa lati fi èsi kan fun ọ nitori ọ̀ran yi. Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba. Ṣugbọn bi bẹ̃kọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa kì yio sìn oriṣa rẹ, bẹ̃li awa kì yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.
Dan 3:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá. Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”
Dan 3:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba. Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”