Dan 3:28
Dan 3:28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn.
Dan 3:28 Yoruba Bible (YCE)
Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn.
Dan 3:28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.