Eks 18:20-21
Eks 18:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe. Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa.
Eks 18:20-21 Yoruba Bible (YCE)
ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe. Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.
Eks 18:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà-bí-Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe. Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá.