Gẹn 6:1-22
Gẹn 6:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn, Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn. OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún. Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí. Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ. Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀. OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA. Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn. Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti. Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara. Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye. Ọlọrun si wi fun Noa pe, Opin gbogbo enia de iwaju mi; nitori ti aiye kún fun ìwa-agbara lati ọwọ́ wọn; si kiye si i, emi o si pa wọn run pẹlu aiye. Iwọ fi igi goferi kàn ọkọ́ kan; ikele-ikele ni iwọ o ṣe ninu ọkọ́ na, iwọ o si fi ọ̀da kùn u ninu ati lode. Bayi ni iwọ o si ṣe e: Ìna ọkọ̀ na yio jẹ ọ̃dunrun igbọ́nwọ, ìbú rẹ̀ ãdọta igbọ́nwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọ̀nwọ. Ferese ni iwọ o si ṣe si ọkọ̀ na ni igbọ́nwọ kan ni ki iwọ ki o si pari wọn loke; lẹgbẹ ni iwọ o si dá ẹnu-ọ̀na ọkọ̀ na, si: pẹlu yara isalẹ, atẹle, ati ẹkẹta loke ni iwọ o ṣe e. Ati emi, wò o, emi nmu kikun-omi bọ̀ wá si aiye, lati pa gbogbo ohun alãye run, ti o li ẹmi ãye ninu kuro labẹ ọrun; ohun gbogbo ti o wà li aiye ni yio si kú. Ṣugbọn iwọ li emi o ba dá majẹmu mi; iwọ o si wọ̀ inu ọkọ̀ na, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati aya rẹ, ati awọn aya awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ. Ati ninu ẹdá alãye gbogbo, ninu onirũru ẹran, meji meji ninu gbogbo ẹran ni iwọ o mu wọ̀ inu ọkọ̀ na, lati mu nwọn là pẹlu rẹ; ti akọ ti abo ni ki nwọn ki o jẹ. Ninu ẹiyẹ nipa irú ti wọn, ninu ẹran-ọ̀sin nipa irú ti wọn, ninu ohun gbogbo ti nrakò ni ilẹ nipa irú tirẹ̀, meji meji ninu gbogbo wọn ni yio ma tọ̀ ọ wá lati mu wọn wà lãye. Iwọ o si mu ninu ohun jijẹ gbogbo, iwọ o si kó wọn jọ si ọdọ rẹ; yio si ṣe onjẹ fun iwọ, ati fun wọn. Bẹ̃ni Noa si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ọlọrun paṣẹ fun u, bẹli o ṣe.
Gẹn 6:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.” Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà. OLúWA sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. Inú OLúWA sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nítorí náà, OLúWA wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere OLúWA. Wọ̀nyí ni ìtàn Noa. Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti. Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà-ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ. Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.” Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.
Gẹn 6:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin, nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn. OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.” Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà. Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA. Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA. Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti. Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé. Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù. Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde. Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú. Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn. Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn. Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ. Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.” Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un.