Gẹn 6:1-4
Gẹn 6:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin, nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn. OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.” Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà.
Gẹn 6:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn, Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn. OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún. Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí.
Gẹn 6:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.” Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.