Hab 3:17-18
Hab 3:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé, tí àjàrà kò sì so, tí kò sí èso lórí igi olifi; tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko, tí àwọn agbo aguntan run, tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́, sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA, n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi.
Pín
Kà Hab 3Hab 3:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ: Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi.
Pín
Kà Hab 3Hab 3:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí igi olifi ko le so, àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá; tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́, síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú OLúWA, èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
Pín
Kà Hab 3