HABAKUKU 3
3
Adura Habakuku
1Adura tí wolii Habakuku kọ lórin#3:1 Bóyá ohùn orin tí wọ́n fi kọ orin yìí ní èdè Heberu ni Ṣigionoti. nìyí:
2OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ,
mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́;
tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa;
sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.
3OLUWA wá láti Temani,
Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani.
Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run,
gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.
4Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,
ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;
níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,
ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.
6Ó dúró, ó wọn ayé;
Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;
àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,
àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.
Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.
7Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu,
àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì.
8OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni,
àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí,
tabi òkun ni ò ń bá bínú,
nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ,
tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?
9Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun,
tí o fi ọfà lé ọsán ọrun;
tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé.
10Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ,
wọ́n wárìrì;
àgbàrá omi wọ́ kọjá;
ibú òkun pariwo,
ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
11Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,
nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,
tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,
bí wọ́n ti ń fò lọ.
12O la ayé kọjá pẹlu ibinu,
o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.
13O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là,
láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là.
O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú,
o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn.
14O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun;
àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle
láti tú wa ká,
tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀.
15O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀;
wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀.
16Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì,
ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀
nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀;
egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà,
ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀.
N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé
bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.
17Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé,
tí àjàrà kò sì so,
tí kò sí èso lórí igi olifi;
tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko,
tí àwọn agbo aguntan run,
tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́,
18sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA,
n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi.
19Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi;
Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,
ó mú mi rìn lórí àwọn òkè gíga.#2Sam 22:34; O. Daf 18:33
(Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.)
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
HABAKUKU 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010