HABAKUKU 2

2
Ìdáhùn OLUWA sí Habakuku
1N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un.
2OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á. 3Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́.#Heb 10:37 4Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”#Rom 1:17; Gal 3:11; Heb 10:38
Ìjìyà Àwọn Alaiṣododo
5Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀. 6Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?”
7Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn? 8Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.
9Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín! 10O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ. 11Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu.
12Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìwà ìpànìyàn kó ìlú jọ, tí ẹ fi ìwà ọ̀daràn tẹ ìlú dó. 13Wò ó, ṣebí ìkáwọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó wà, pé kí orílẹ̀-èdè kan ṣe làálàá tán, kí iná sì jó gbogbo rẹ̀ ní àjórun, kí wahala orílẹ̀-èdè náà sì já sí asán.#Sir 14:19 14Nítorí ayé yóo kún fún ìmọ̀ ògo OLUWA, gẹ́gẹ́ bí omi ti kún inú òkun.#Ais 11:9
15Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ fi ibinu fún aládùúgbò yín ní ọtí mu, tí ẹ jẹ́ kí inú wọn ru, kí ẹ lè rí ìhòòhò wọn. 16Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín. 17Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.
18Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀! 19Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá.
20Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HABAKUKU 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀