Heb 11:13-16
Heb 11:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye. Nitoripe awọn ti o nsọ irú ohun bẹ̃, fihan gbangba pe, nwọn nṣe afẹri ilu kan ti iṣe tiwọn. Ati nitõtọ, ibaṣepe nwọn fi ilu tí nwọn ti jade wa si ọkàn, nwọn iba ti ri aye lati pada. Ṣugbọn nisisiyi nwọn nfẹ ilu kan ti o dara jù bẹ̃ lọ, eyini ni ti ọ̀run: nitorina oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mã pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn.
Heb 11:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé. Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ. Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn.
Heb 11:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.