Heb 11
11
Igbagbọ
1NJẸ igbagbọ́ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri.
2Nitori ninu rẹ̀ li awọn alàgba ti ni ẹri rere.
3Nipa igbagbọ́ li a mọ̀ pe a ti da aiye nipa ọ̀rọ Ọlọrun; nitorina ki iṣe ohun ti o hàn li a fi dá ohun ti a nri.
4Nipa igbagbọ́ ni Abeli ru ẹbọ si Ọlọrun ti o san ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rẹ̀ pe olododo ni, Ọlọrun si njẹri ẹ̀bun rẹ̀: ati nipa rẹ̀ na, bi o ti kú ni, o nfọhùn sibẹ̀.
5Nipa igbagbọ́ li a ṣí Enoku nipò pada ki o máṣe ri ikú; a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣí i nipò pada: nitori ṣaju iṣipopada rẹ̀, a jẹrí yi si i pe o wù Ọlọrun.
6Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.
7Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́.
8Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.
9Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀:
10Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́.
11Nipa igbagbọ́ ni Sara tikararẹ̀ pẹlu fi ni agbara lati lóyun, nigbati o kọja ìgba rẹ̀, nitoriti o kà ẹniti o ṣe ileri si olõtọ.
12Nitorina li ọ̀pọlọpọ ṣe ti ara ẹnikan jade, ani ara ẹniti o dabi okú, ọ̀pọ bi irawọ oju ọrun li ọ̀pọlọpọ, ati bi iyanrin eti okun li ainiye.
13Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye.
14Nitoripe awọn ti o nsọ irú ohun bẹ̃, fihan gbangba pe, nwọn nṣe afẹri ilu kan ti iṣe tiwọn.
15Ati nitõtọ, ibaṣepe nwọn fi ilu tí nwọn ti jade wa si ọkàn, nwọn iba ti ri aye lati pada.
16Ṣugbọn nisisiyi nwọn nfẹ ilu kan ti o dara jù bẹ̃ lọ, eyini ni ti ọ̀run: nitorina oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mã pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn.
17Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a dán a wò, fi Isaaki rubọ: ẹniti o si ti fi ayọ̀ gbà ileri wọnni fi ọmọ-bíbi rẹ̀ kanṣoṣo rubọ.
18Niti ẹniti a wipe, Ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ:
19O si pari rẹ̀ si pe Ọlọrun tilẹ le gbe e dide, ani kuro ninu oku, ati ibiti o ti gbà a pada pẹlu ni apẹrẹ.
20Nipa igbagbọ́ ni Isaaki sure fun Jakọbu ati Esau niti ohun ti mbọ̀.
21Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀.
22Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀.
23Nipa igbagbọ́ ni awọn obi Mose pa a mọ́ fun oṣu mẹta nigbati a bí i, nitoriti nwọn ri i ni arẹwa ọmọ; nwọn kò si bẹ̀ru aṣẹ ọba.
24Nipa igbagbọ́ ni Mose, nigbati o dàgba, o kọ̀ ki a mã pè on li ọmọ ọmọbinrin Farao;
25O kuku yàn ati mã bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù ati jẹ fãji ẹ̀ṣẹ fun igba diẹ;
26O kà ẹ̀gan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo ère na.
27Nipa igbagbọ́ li o kọ̀ Egipti silẹ li aibẹ̀ru ibinu ọba: nitoriti o duro ṣinṣin bi ẹniti o nri ẹni airi.
28Nipa igbagbọ́ li o dá ase irekọja silẹ, ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ, ki ẹniti npa awọn akọbi ọmọ ki o má bã fi ọwọ́ kàn wọn.
29Nipa igbagbọ́ ni nwọn là okun pupa kọja bi ẹnipe ni iyangbẹ ilẹ: ti awọn ara Egipti danwò, ti nwọn si rì.
30Nipa igbagbọ́ li awọn odi Jeriko wó lulẹ, lẹhin igbati a yi wọn ká ni ijọ meje.
31Nipa igbagbọ́ ni Rahabu panṣaga kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbati o tẹwọgbà awọn amí li alafia.
32Ewo li emi o si tun mã wi si i? nitoripe ãyè kò ni tó fun mi lati sọ ti Gideoni, ati Baraku, ati Samsoni, ati Jefta; ti Dafidi, ati Samueli, ati ti awọn woli:
33Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ́ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu,
34Ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ́ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, ti nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá.
35Awọn obinrin ri okú wọn gbà nipa ajinde: a si dá awọn ẹlomiran lóro, nwọn kọ̀ lati gbà ìdasilẹ; ki nwọn ki o le ri ajinde ti o dara jù gbà:
36Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu:
37A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro;
38Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ.
39Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere sí nipa igbagbọ́, nwọn kò si ri ileri na gbà:
40Nitori Ọlọrun ti pèse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a má ṣe wọn pé.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Heb 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.