Heb 10
10
1NITORI ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ̀ laijẹ aworan pãpã awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọ̃dún mu awọn ti nwá sibẹ̀ di pipé.
2Bikoṣe bẹ̃, a kì bá ha ti dẹkun ati mã rú wọn, nitori awọn ti nsìn kì bá tí ni ìmọ ẹ̀ṣẹ, nigbati a ba ti wẹ wọn mọ lẹ̃kanṣoṣo.
3Ṣugbọn ninu ẹbọ wọnni ni a nṣe iranti ẹ̀ṣẹ li ọdọdún.
4Nitori ko ṣe iṣe fun ẹ̀jẹ akọ malu ati ti ewurẹ lati mu ẹ̀ṣẹ kuro.
5Nitorina nigbati o wá si aiye, o wipe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pèse fun mi:
6Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si.
7Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun.
8Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin).
9Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ.
10Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo.
11Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai:
12Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun;
13Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀.
14Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.
15Ẹmí Mimọ́ si njẹri fun wa pẹlu: nitori lẹhin ti o ti wipe,
16Eyi ni majẹmu ti emi ó ba wọn dá lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si wọn li ọkàn, inu wọn pẹlu li emi o si kọ wọn si;
17Ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.
18Ṣugbọn nibiti imukuro iwọnyi ba gbé wà, irubọ fun ẹ̀ṣẹ kò si mọ́.
Ọ̀rọ̀ Ìyànjú ati Ìkìlọ̀
19Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu,
20Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;
21Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun;
22Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.
23Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)
24Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere:
25Ki a má mã kọ ipejọpọ̀ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile.
26Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́,
27Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run.
28Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta:
29Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ.
30Nitori awa mọ̀ ẹniti o wipe, Ẹsan ni ti emi, Oluwa wipe, Emi o gbẹsan. Ati pẹlu, Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀.
31Ohun ẹ̀ru ni lati ṣubu si ọwọ́ Ọlọrun alãye.
32Ṣugbọn ẹ ranti ọjọ iṣaju, ninu eyiti, nigbati a ti ṣí nyin loju, ẹ fi ara da wahala ijiya nla;
33Lapakan, nigbati a sọ nyin di iran wiwo nipa ẹ̀gan ati ipọnju; ati lapakan, nigbati ẹnyin di ẹgbẹ awọn ti a ṣe bẹ̃ si.
34Nitori ẹnyin bá awọn ti o wà ninu ìde kẹdun, ẹ si fi ayọ̀ gbà ìkolọ ẹrù nyin, nitori ẹnyin mọ̀ ninu ara nyin pe, ẹ ni ọrọ̀ ti o wà titi, ti o si dara ju bẹ̃ lọ li ọ̀run.
35Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla.
36Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na.
37Nitori niwọn igba diẹ si i, Ẹni nã ti mbọ̀ yio de, kì yio si jafara.
38Ṣugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ́: ṣugbọn bi o ba fà sẹhin, ọkàn mi kò ni inu didùn si i.
39Ṣugbọn awa kò si ninu awọn ti nfà sẹhin sinu egbé; bikoṣe ninu awọn ti o gbagbọ́ si igbala ọkàn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Heb 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.