Isa 20:3-4
Isa 20:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si wipe, Gẹgẹ bi Isaiah iranṣẹ mi ti rìn nihòho ati laibọ̀ bàta li ọdun mẹta fun ami ati iyanu lori Egipti ati lori Etiopia; Bẹ̃li ọba Assiria yio kó awọn ara Egipti ni igbèkun ati awọn ara Etiopia ni igbèkun, ọmọde ati arugbo, nihòho ati laibọ̀ bàta, ani ti awọn ti idí wọn nihòho, si itiju Egipti.
Isa 20:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọdún mẹta, OLUWA dáhùn pé, “Bí Aisaya, iranṣẹ mi, ti rìn ní ìhòòhò tí kò sì wọ bàtà fún ọdún mẹta yìí, jẹ́ àmì ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kuṣi: Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti.
Isa 20:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni OLúWA wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí ààmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti.