Isa 42:16
Isa 42:16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.
Pín
Kà Isa 42Isa 42:16 Yoruba Bible (YCE)
“N óo darí àwọn afọ́jú, n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí, n óo tọ́ wọn sọ́nà, ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí. N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn, n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú. N óo ṣe àwọn nǹkan, n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Pín
Kà Isa 42Isa 42:16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Pín
Kà Isa 42