Isaiah 42
42
Ìránṣẹ́ Olúwa náà
1 “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,
àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;
Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀
òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
2Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè,
tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.
3Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
4òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì
títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé.
Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”
5 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí
Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
6 “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;
Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
7 láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
8“Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn
tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
9Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,
àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;
kí wọn tó hù jáde
mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
Orin ìyìn sí Olúwa
10Kọ orin tuntun sí Olúwa
ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,
ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti
ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀
ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.
11Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè;
jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi Kedari ń gbé máa yọ̀.
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀;
jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.
12Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa
àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
13 Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,
yóò ru owú sókè bí ológun;
yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun,
òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.
14“Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,
mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,
mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
15Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro
tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù;
Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù
n ó sì gbẹ àwọn adágún.
16Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,
ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;
Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn
àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.
Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;
Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
17Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,
tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’
ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
Israẹli fọ́jú ó dití
18“Gbọ́, ìwọ adití,
wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
19Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,
àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?
Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,
ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
20Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;
etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”
21Ó dùn mọ́ Olúwa
nítorí òdodo rẹ̀
láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.
22Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun
tí a sì kó lẹ́rú,
gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,
tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.
Wọ́n ti di ìkógun,
láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;
wọ́n ti di ìkógun,
láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
23Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí
tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?
24Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun,
àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?
Kì í ha ṣe Olúwa ni,
ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?
Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;
wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.
25Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,
rògbòdìyàn ogun.
Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀
èdè kò yé wọn;
ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isaiah 42: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.