“Èmi, OLúWA, ti pè ọ́ ní òdodo;
Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.