1
Isaiah 43:19
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 43:19
2
Isaiah 43:2
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
Ṣàwárí Isaiah 43:2
3
Isaiah 43:18
“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
Ṣàwárí Isaiah 43:18
4
Isaiah 43:1
Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí OLúWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
Ṣàwárí Isaiah 43:1
5
Isaiah 43:4
Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
Ṣàwárí Isaiah 43:4
6
Isaiah 43:3
Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ, Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
Ṣàwárí Isaiah 43:3
7
Isaiah 43:5
Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
Ṣàwárí Isaiah 43:5
8
Isaiah 43:25
“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
Ṣàwárí Isaiah 43:25
9
Isaiah 43:10
“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
Ṣàwárí Isaiah 43:10
10
Isaiah 43:11
Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLúWA, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
Ṣàwárí Isaiah 43:11
11
Isaiah 43:13
Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
Ṣàwárí Isaiah 43:13
12
Isaiah 43:20-21
Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
Ṣàwárí Isaiah 43:20-21
13
Isaiah 43:6-7
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
Ṣàwárí Isaiah 43:6-7
14
Isaiah 43:16-17
Èyí ni ohun tí OLúWA wí Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi, ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà
Ṣàwárí Isaiah 43:16-17
15
Isaiah 43:15
Èmi ni OLúWA, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
Ṣàwárí Isaiah 43:15
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò