Isa 42:6-7
Isa 42:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú, mo sì pa ọ́ mọ́. Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé, mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; kí o lè la ojú àwọn afọ́jú, kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́, kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Isa 42:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi. Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu.
Isa 42:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi, OLúWA, ti pè ọ́ ní òdodo; Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.