Isa 45:5-6
Isa 45:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi. Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran.
Pín
Kà Isa 45Isa 45:5-6 Yoruba Bible (YCE)
“Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí. Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
Pín
Kà Isa 45Isa 45:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ni OLúWA, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni OLúWA, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
Pín
Kà Isa 45