AISAYA 45
45
OLUWA Yan Kirusi
1Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí:
Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò,
láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
láti tú àmùrè àwọn ọba,
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀,
kí ẹnubodè má lè tì.
2OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ,
n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,
n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.
3N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn,
ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀;
kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli,
ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.
4Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi,
ati Israẹli, àyànfẹ́ mi,
mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.
Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.
5“Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn,
kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí.
6Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,
kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
7Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,
èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:
Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
8Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run,
kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde.
Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu,
èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀.
OLUWA Ẹlẹ́dàá Ayé ati Ìtàn
9“Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé!#Ais 29:16; Rom 9:20
Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà.
Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé:
‘Kí ni ò ń mọ?’
Tabi kí ó sọ fún un pé,
‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’
10Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:
‘Irú kí ni o bí?’
Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:
‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’
Olúwarẹ̀ gbé!”
11OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,
“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,
tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?
12Èmi ni mo dá ayé,
tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,
tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.
13Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi,
n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́;
òun ni yóo tún ìlú mi kọ́,
yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀,
láìgba owó ati láìwá èrè kan.”
OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
14Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,
ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,
wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,
wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.
Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,
wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.
Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,
‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,
kò tún sí Ọlọrun mìíràn.
Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”
15Nítòótọ́,
ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,
Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.
16Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,
ìdààmú yóo sì bá wọn.
Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère
yóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.
17Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là,
títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀.
Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae.
18Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,
OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.)
Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀,
kò dá a ninu rúdurùdu,
ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀
Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.
19N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.
N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:
‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’
Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.
Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”
OLUWA Gbogbo Ayé ati Àwọn Oriṣa Babiloni
20OLUWA ní:
“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,
ẹ jọ súnmọ́ bí,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.
Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,
tí wọ́n sì ń gbadura
sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.
21Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín,
jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀.
Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae?
Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?
Ṣebí èmi OLUWA ni?
Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.
Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà
kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.
22“Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là,
gbogbo ẹ̀yin òpin ayé.
Nítorí èmi ni Ọlọrun,
kò tún sí ẹlòmíràn mọ́.
23Mo ti fi ara mi búra,#Rom 14:11; Fil 2:10-11
mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú,
ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada:
‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi,
èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’
24“Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé,
‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’
Gbogbo àwọn tí ń bá a bínú
yóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú.
25Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun,
wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 45: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010