1
AISAYA 45:3
Yoruba Bible
N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn, ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀; kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 45:3
2
AISAYA 45:2
OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ, n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀; n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.
Ṣàwárí AISAYA 45:2
3
AISAYA 45:5-6
“Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí. Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
Ṣàwárí AISAYA 45:5-6
4
AISAYA 45:7
Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn, èmi ni mo dá alaafia ati àjálù: Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
Ṣàwárí AISAYA 45:7
5
AISAYA 45:22
“Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin òpin ayé. Nítorí èmi ni Ọlọrun, kò tún sí ẹlòmíràn mọ́.
Ṣàwárí AISAYA 45:22
6
AISAYA 45:1
Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí: Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò, láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀, láti tú àmùrè àwọn ọba, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀, kí ẹnubodè má lè tì.
Ṣàwárí AISAYA 45:1
7
AISAYA 45:23
Mo ti fi ara mi búra, mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú, ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada: ‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi, èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’
Ṣàwárí AISAYA 45:23
8
AISAYA 45:4
Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi, ati Israẹli, àyànfẹ́ mi, mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.
Ṣàwárí AISAYA 45:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò