Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Isa 5:24YBCV(Bibeli Mimọ)
Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli.
Pín
Isa 5YBCVIsa 5:24BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin OLúWA àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
Pín
Isa 5BMYOIsa 5:24YCE(Yoruba Bible)
Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀, tíí sìí jó ewéko ní àjórun; bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà, tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku. Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Pín
Isa 5YCE