AISAYA 5
5
Orin Ọgbà Àjàrà
1Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi,
kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
ní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá.
2Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò.#Mat 21:33; Mak 12:1; Luk 20:9
Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,
ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.
Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,
ṣugbọn èso kíkan ni ó so.
3Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,
mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.
4Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?
Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,
kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?
5Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.
N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,
iná yóo sì jó o.
N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,
wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
6N óo jẹ́ kí ó di igbó,
ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,
wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.
Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.
N óo pàṣẹ fún òjò
kí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.
7Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,
àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.
Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,
ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;
ó ń retí ìwà òdodo,
ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.
Ìwà Burúkú Eniyan
8Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,
tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,
títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,
kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà.
9OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,
“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,
ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.
10Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá.
Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.”
11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,
láti máa wá ọtí líle kiri,
tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,
títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!
12Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;
ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,
wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.#Ọgb 2:7-9
13Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,
ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,
òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.
14Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,
ó ti yanu kalẹ̀.
Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,
ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,
ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.
15A tẹ eniyan lórí ba,
a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀
ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀.
16Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogun
ni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodo
Ọlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo.
17Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọn
àwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.
18Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!
Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.
19Tí wọn ń wí pé:
“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,
kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.
Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́
kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”
20Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;
tí wọn ń pe ire ní ibi!
Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,
tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!
Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,
tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò.
21Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;
tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!
22Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;
tí wọ́n jẹ́ akikanju
bí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn!
23Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀
nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;
tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà.
24Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,
tíí sìí jó ewéko ní àjórun;
bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,
tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.
Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,
wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.
25Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,
ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n,
àwọn òkè sì mì tìtì.
Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro,
sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.
26Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè;
ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé.
Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá.
27Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn,
ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ.
Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé.
Àmùrè ẹnìkankan kò tú,
bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já.
28Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn.
Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ;
ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle.
29Bíbú wọn dàbí ti kinniun,
wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun,
wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀,
wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn.
30Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náà
bí ìgbà tí omi òkun ń hó.
Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira.
Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 5: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010