AISAYA 6

6
Ọlọrun Pe Aisaya láti jẹ́ Wolii
1Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.#2A. Ọba 15:7; 2Kron 26:23 2Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. 3Ekinni ń ké sí ekeji pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun;
gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”#Ifi 4:8
4Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà. 5Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”#Ifi 15:8
6Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi. 7Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” 8Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”
Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”
9OLUWA bá ní:
“Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé;
wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn;
wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan.
10Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì,#Mat 13:14-15; Mak 4:12; Luk 8:10; Joh 12:40; A. Apo 28: 26-27
jẹ́ kí etí wọn di.
Fi nǹkan bò wọ́n lójú,
kí wọn má baà ríran,
kí wọn má sì gbọ́ràn,
kí òye má baà yé wọn,
kí wọn má baà yipada,
kí wọn sì rí ìwòsàn.”
11Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?”
Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata. 12Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà. 13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.”
Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀