1
AISAYA 6:8
Yoruba Bible
Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 6:8
2
AISAYA 6:3
Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
Ṣàwárí AISAYA 6:3
3
AISAYA 6:5
Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”
Ṣàwárí AISAYA 6:5
4
AISAYA 6:1
Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.
Ṣàwárí AISAYA 6:1
5
AISAYA 6:7
Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
Ṣàwárí AISAYA 6:7
6
AISAYA 6:2
Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò.
Ṣàwárí AISAYA 6:2
7
AISAYA 6:6
Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.
Ṣàwárí AISAYA 6:6
8
AISAYA 6:9
OLUWA bá ní: “Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé; wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn; wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan.
Ṣàwárí AISAYA 6:9
9
AISAYA 6:10
Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì, jẹ́ kí etí wọn di. Fi nǹkan bò wọ́n lójú, kí wọn má baà ríran, kí wọn má sì gbọ́ràn, kí òye má baà yé wọn, kí wọn má baà yipada, kí wọn sì rí ìwòsàn.”
Ṣàwárí AISAYA 6:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò