Job 2:10 - Compare All Versions

Job 2:10 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.

Job 2:10 YCE (Yoruba Bible)

Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ.

Job 2:10 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.