Job 2:11-13
Job 2:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.
Job 2:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati awọn ọrẹ Jobu mẹta gburo gbogbo ibi ti o ba a, nwọn wá, olukuluku lati ibujoko rẹ̀ wá; Elifasi, ara Tema, a si Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama: nitoripe nwọn ti dajọ ipade pọ̀ lati ba a ṣọ̀fọ on ati ṣipẹ fun u. Nigbati nwọn si gboju wọn wò li òkere rére, ti nwọn kò si mọ̀ ọ, nwọn gbe ohùn wọn soke, nwọn sọkun: olukuluku si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, nwọn si kù erupẹ si oju ọrun si ara wọn lori. Bẹ̃ni nwọn joko tì i ni ilẹyilẹ ni ijọ meje ti ọ̀san ti oru, ẹnikẹni kò si ba a dá ọ̀rọ kan sọ nitoriti nwọn ri pe, ibinujẹ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.
Job 2:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha ati Sofari ará Naama, àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹta, gbọ́ nípa ìyọnu tí ó dé bá Jobu, wọ́n wá láti kí i, ati láti tù ú ninu. Nígbà tí wọ́n rí Jobu ní ọ̀ọ́kán, wọn kò mọ̀ ọ́n mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n súnmọ́ ọn tí wọ́n mọ̀ pé òun ni, wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì ku eruku sórí. Wọ́n jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, tọ̀sán-tòru, láìsọ nǹkankan, nítorí pé wọ́n rí i bí ìrora náà ti pọ̀ tó.