Mal 2:16 - Compare All Versions
Mal 2:16 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.
Pín
Mal 2 YBCVMal 2:16 YCE (Yoruba Bible)
“Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Pín
Mal 2 YCEMal 2:16 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọkùnrin tí ó bá kórìíra, tí ó sì kọ ìyàwó rẹ̀,” se ìwà ipá sí ẹni tí ó yẹ kí ó dá ààbò bò, ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má ṣe hùwà ẹ̀tàn.
Pín
Mal 2 BMYO