Mal 2

2
1NJẸ nisisiyi, ẹnyin alufa, ofin yi ni fun nyin.
2Bi ẹnyin kì o ba gbọ́, ti ẹnyin kì o ba fi si aiya, lati fi ogo fun orukọ mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si rán egún si ori nyin, emi o si fi ibukun nyin ré, lõtọ mo ti fi ré na, nitori pe, ẹnyin kò fi i si ọkàn.
3Wò o, emi o ba irugbìn nyin jẹ, emi o si fi igbẹ́ rẹ́ nyin loju, ani igbẹ́ asè ọ̀wọ nyin wọnni; a o si kó nyin lọ pẹlu rẹ̀.
4Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li o ti rán ofin yi si nyin, ki majẹ̀mu mi le wà pẹlu Lefi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
5Majẹmu mi ti iyè on alafia wà pẹlu rẹ̀; mo si fi wọn fun u, nitori bibẹ̀ru ti o bẹ̀ru mi, ti ẹ̀ru orukọ mi si bà a.
6Ofin otitọ wà li ẹnu rẹ̀, a kò si ri ìwa-buburu li etè rẹ̀: o ba mi rìn li alafia ati ni ododo, o si yi ọ̀pọlọpọ kuro ninu ìwa-buburu.
7Nitori ète alufa iba ma pa ìmọ mọ, ki nwọn ki o si ma wá ofin li ẹnu rẹ̀: nitori onṣẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun li on iṣe.
8Ṣugbọn ẹnyin ti yapa kuro li ọ̀na na: ẹnyin ti mu ọ̀pọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
9Nitorina li emi pẹlu ṣe sọ nyin di ẹ̀gan, ati ẹni aikàsi niwaju gbogbo enia, niwọ̀n bi ẹnyin kò ti pa ọ̀na mi mọ, ti ẹnyin si ti nṣe ojusaju ninu ofin.
Aiṣootọ Àwọn Eniyan sí Ọlọrun
10Baba kanna ki gbogbo wa ha ni? Ọlọrun kanna kó ha da wa bi? nitori kili awa ha ṣe nhùwa arekerekè olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́.
11Juda ti nhùwa arekerekè, a si ti nhùwa irira ni Israeli ati ni Jerusalemu: nitori Juda ti sọ ìwa mimọ́ Oluwa di alaimọ́, eyi ti o fẹ, o si ti gbe ọmọbinrin ọlọrun ajeji ni iyàwo.
12Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olukọ ati ẹniti a nkọ, kuro ninu agọ Jakobu wọnni, ati ẹniti nrubọ ọrẹ si Oluwa awọn ọmọ-ogun.
13Eyi li ẹnyin si tún ṣe, ẹnyin fi omije, ati ẹkún, ati igbe, bò pẹpẹ Oluwa mọlẹ, tobẹ̃ ti on kò fi kà ọrẹ nyin si mọ, tabi ki o fi inu-didùn gbà nkan lọwọ nyin.
14Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ.
15On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀.
16Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.
Ọjọ́ Ìdájọ́ Súnmọ́lé
17Ẹnyin ti fi ọ̀rọ nyin dá Oluwa li agara. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kini awa fi da a lagara? Nigbati ẹnyin wipe, Olukulùku ẹniti o ṣe ibi, rere ni niwaju Oluwa, inu rẹ̀ si dùn si wọn; tabi, nibo ni Ọlọrun idajọ gbe wà?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mal 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀