Mal 3
3
1KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
2Ṣugbọn tali o le gbà ọjọ wíwa rẹ̀? tani yio si duro nigbati o ba fi ara hàn? nitori on dabi iná ẹniti ndà fadakà, ati bi ọṣẹ afọṣọ:
3On o si joko bi ẹniti nyọ́, ti o si ndà fadakà: yio si ṣe awọn ọmọ Lefi mọ́, yio si yọ́ wọn bi wurà on fadakà, ki nwọn ki o le mu ọrẹ ododo wá fun Oluwa.
4Nigbana ni ọrẹ Juda ati ti Jerusalemu yio wù Oluwa, gẹgẹ bi ti ọjọ igbãni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ.
5Emi o si sunmọ nyin fun idajọ, emi o si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eké, ati awọn ti o ni alagbaṣe lara ninu ọyà rẹ̀, ati opo, ati alainibaba, ati si ẹniti o nrẹ́ alejo jẹ, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Sísan ìdámẹ́wàá
6Nitori Emi li Oluwa, Emi kò yipada; nitorina li a kò ṣe run ẹnyin ọmọ Jakobu.
7Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada?
8Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ.
9Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi.
10Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a.
11Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
12Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Ìlérí Àánú Tí Ọlọrun Ṣe
13Ọ̀rọ nyin ti jẹ lile si mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ọ̀rọ kili awa sọ si ọ?
14Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?
15Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si.
16Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.
17Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá; emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti ma dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i.
18Nigbana li ẹnyin o yipada, ẹ o si mọ̀ iyatọ̀ lãrin olododo ati ẹni-buburu, lãrin ẹniti nsìn Ọlọrun, ati ẹniti kò sìn i.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mal 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.