Neh 1:5-6
Neh 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ: Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀.
Neh 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)
“OLUWA Ọlọrun ọ̀run, Ọlọrun tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, Ọlọrun tíí máa pa majẹmu ati ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ mọ́ pẹlu àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀.
Neh 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni mo wí pé: “OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́. Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.