Num 16:1-2
Num 16:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ: Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí
Num 16:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Kora ọmọ Iṣari láti inú ìdílé Kohati ọmọ Lefi, pẹlu Datani ati Abiramu àwọn ọmọ Eliabu, pẹlu Ooni ọmọ Peleti láti inú ẹ̀yà Reubẹni gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose.
Num 16:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kora ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi àwọn ọmọ Reubeni: Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, àti Oni ọmọ Peleti mú ènìyàn mọ́ra. Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.