Num 16:30-32
Num 16:30-32 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí OLUWA bá ṣe ohun tí etí kò gbọ́ rí, tí ilẹ̀ bá yanu tí ó gbé wọn mì pẹlu àwọn eniyan wọn ati àwọn ohun ìní wọn, tí wọn sì bọ́ sinu ibojì láàyè, ẹ óo mọ̀ pé wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀.” Ní kété tí Mose parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí là sí meji, ó yanu, ó sì gbé wọn mì, ati àwọn ati ìdílé wọn, ati ohun ìní wọn. Ilẹ̀ sì gbé Kora mì pẹlu àwọn eniyan rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní wọn.
Num 16:30-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi OLUWA ba ṣe ohun titun, ti ilẹ ba si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, pẹlu ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, ti nwọn si sọkalẹ lọ si ipò-okú lãye; nigbana ẹnyin o mọ̀ pe awọn ọkunrin wọnyi ti gàn OLUWA. O si ṣe, bi o ti pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni sisọ, ni ilẹ là pẹrẹ nisalẹ wọn: Ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si gbe wọn mì, ati awọn ara ile wọn, ati gbogbo awọn enia ti iṣe ti Kora, ati gbogbo ẹrù wọn.
Num 16:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí OLúWA bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn OLúWA.” Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn, ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kora àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.