O. Daf 17:1-15

O. Daf 17:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade. Jẹ ki idajọ mi ki o ma ti iwaju rẹ jade wá: jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ohun ti o ṣe dẽde. Iwọ ti dan aiya mi wò; iwọ ti bẹ̀ ẹ wò li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan; emi ti pinnu rẹ̀ pe, ẹnu mi kì yio ṣẹ̀. Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun. Fi ìrin mi le ilẹ ni ipa rẹ, ki atẹlẹ ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi: Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn. Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ, Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri. Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga. Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ: Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ. Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ: Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn. Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.

O. Daf 17:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi; fi ìtara gbọ́ igbe mi. Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá; kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru. Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan; n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà; ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn, dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu, fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú, dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ; lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí, àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Ojú àánú wọn ti fọ́, ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí; wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ, àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀; fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi; àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí, fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́; jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó; sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ. Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi, ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.

O. Daf 17:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbọ́, OLúWA, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi; fi etí sí igbe mi. Tẹ́tí sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde. Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ; kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀. Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi. Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́, wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga. Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká, pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀. Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ, àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀. Dìde, OLúWA, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ. OLúWA, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.