ORIN DAFIDI 17:1-15

ORIN DAFIDI 17:1-15 YCE

Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi; fi ìtara gbọ́ igbe mi. Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá; kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru. Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan; n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà; ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn, dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu, fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú, dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ; lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí, àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Ojú àánú wọn ti fọ́, ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí; wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ, àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀; fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi; àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí, fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́; jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó; sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ. Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi, ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.