GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade.
Jẹ ki idajọ mi ki o ma ti iwaju rẹ jade wá: jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ohun ti o ṣe dẽde.
Iwọ ti dan aiya mi wò; iwọ ti bẹ̀ ẹ wò li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan; emi ti pinnu rẹ̀ pe, ẹnu mi kì yio ṣẹ̀.
Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun.
Fi ìrin mi le ilẹ ni ipa rẹ, ki atẹlẹ ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.
Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi:
Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn.
Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ,
Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri.
Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga.
Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ:
Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ.
Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ:
Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn.
Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.