Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

O. Daf 63:6-8YBCV(Bibeli Mimọ)

Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru. Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀. Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró.

O. Daf 63:6-8BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

O. Daf 63:6-8YCE(Yoruba Bible)

Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi, tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru; nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ; ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.