Rom 16:25-27
Rom 16:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye, Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́: Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.
Rom 16:25-27 Yoruba Bible (YCE)
Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà. Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin.
Rom 16:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.