Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?Àpẹrẹ

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ọjọ́ 4 nínú 5

Kí Ni Mo Lè Ṣe Nígbàtí A Bá Dán Mi Wò?

Gbé e tọ Ọlọ́run lọ—nísinsìnyí

Nígbà tí a bá dán ẹ wò, rántí ìlérí yìí: “Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.” (Kọ́ríńtì kíní 10:13 BM).

Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ìdánwò tó kọjá agbára wa dé bá wa. Bákan náà, Sátánì ò ní fi àkókò rẹ̀ ṣòfò láti dán wa wò pẹ̀lú ǹkan tí a lè borí pẹ̀lú ipá tiwa. 

Fún ìdí èyí, gbogbo ìgbà tí a bá dán ẹ wò, mọ̀ dájú wípé o kò lè borí ìjàkadì náà nípa agbára tìrẹ. 

Wà ní ìgbáradì láti jọ̀wọ́ gbogbo ìdánwò rẹ fún Baba lójú ẹsẹ̀.  

Tọrọ fún agbára Rẹ̀. 

Jọ̀wọ́ ohun gbogbo sí ìkápá Rẹ̀. 

Mú u tọ Ọlọ́run lọ—nísinsìnyí.

Ṣe àgbéyẹ̀wò àbájáde náà

Tí o kò bá tẹ̀lé àmọ̀ràn yí?

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa ni Ọlọ́run ma dá'jọ́ lé lórí: “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu. (Oníwàásù 12:14 BM).

Jésù kì wá nílọ̀: “Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.” (Lúùkù 12:2‭-‬3 BM).

A ma dá wa lẹ́jọ́ nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wa: “Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ. Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.” (Mátíù 12:36‭-‬37 BM).

Lẹ́yìn tí ó ka onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ tí a kọ̀ láti jẹ́wọ́, Pétérù wá sọ wípé gbogbo àwọn tó bá ńṣe ǹkan wọ̀nyí “yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú.” (Pétérù kíní 4:5 BM).

Kí ni ó ma ṣẹlẹ̀ sí wọn?

“Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti ìṣe. . . . Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja.” (Kọ́ríńtì kíní 3:13, 15 BM).

Àìwà-bí-Ọlọ́run, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò jẹ́wọ́, àwọn èrò, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ wa ni a ó fi lé'de lọ́jọ́ ìdájọ́ tí gbogbo rẹ̀ yóò sì jó dànù. Nítorí ibi pípé ni ọ̀run jẹ́, àwọn ǹkan wọ̀nyí kò lè wọnú rẹ̀—a gbọ́dọ̀ jó wọn run kí wọn ó sì ṣègbé.

A wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù èrè sì ti bọ́ sọnù.

Nígbàtí a bá dán ẹ wò tí ó sì ṣe ọ́ bíi kí o bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, má ṣe sá kúrò ní iwájú Rẹ̀. 

Ní àkókò àìní rẹ yìí, sá tọ Ọlọ́run lọ.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Can I Really Overcome Sin and Temptation?

Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.

More

A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Denison Forum fún ìpèsè ètò yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.denisonforum.org