Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ọjọ́ 1 nínú 6

Kín ni Èrèdí?

A lè pe èrèdí ní iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti rán ọ láti parí, tàbí ìṣòro ní ayé tí a rán ọ láto yanjú. O jẹ́ iṣẹ́-ọwọ́ Ọlọ́run, tí a ṣẹ̀dá nínú Kristi Jesu láti ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè sáájú fún ọ láti ṣe.

Bẹ́ẹ̀ ni, bí o bá fẹ́ ní òye èrèdí ọjà kan, bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó ṣe é. Ìdí nìyẹn tí àwọn olùpèsè ọjà fi máa ń ṣe ìwé-atọ́nà láti ṣe àlàyé ìṣiṣẹ́ àwọn ọjà wọn. Olọ́run ni olùpèsè wa àti ẹni tí ó ṣe wá, ìwé-atanà Rẹ̀ fún ayé was ì ni Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà a máa ń wo káàkiri ju ọ̀dọ̀ Aṣẹ̀dá wa lọ, láti ní òye èrèdí wa.

Nítorí náà, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ṣíṣe àwárí èrèdí ni níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi àti wíwọ inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lọ. kíka ìgbésí-ayé àwọn ẹlòmíràn lórí ìkànnì tọ́rọ́ńfọ́nkálé (social media) kì yóò dari rẹ súnmọ́ ìpè Ọlọ́run lórí ayé rẹ. Wà á wọnú èrèdí lọ nígà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá di ìwé-atọ́nà fún ọ.

Ó tún ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé kì í ṣe lẹ́yìn ìṣẹ̀dá nǹkan ni a tó máa ń pète èrèdí rẹ̀ bíkòṣe ṣáájú rẹ̀. Èyí túms sí pé Ọlọ́run ní èrèdí rẹ lọ́kàn kí ó tó dá Ọ. Ó sọ fún Jeremiah, ‘Kí èmi kí ó tó dá ọ ní inú, èmí ti mọ̀ ọ́; kí ìwọ kí ó sì tó ti inú jade w ani èmí ti sọ ọ́ di mímọ́, èmí sì yà ọ́ sọ́tọ̀ láti jẹ́ wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè’ Nígbà tí ayé bá ju òkúta ìdènà sọ́nà rẹ, ó jẹ́ ìyànjú láti rántí pé kí á tó bí ọ, Ọlọ́run mọ̀ ọ́, ó sì ti ṣètò èrèdí rẹ.

Ètò sàtánì ni láti jí èrèdí yẹn. yóò lo àwọn ìkùnà àti ìjákulẹ̀ rẹ̀ láti jẹ́ kí o rò pé o kò yẹ fún mímú àyànmọ́ rẹ ṣẹ. Nígbà tí àwọn àkọlù yẹn bá wá, sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jade. Taa ni Ọlọ́run sọ pé o jẹ́? Máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun mìíràn fún ọ.

Jeremiah wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbésí-ayé rẹ̀, ó sì ṣe àwáwí fún àìsin Ọlọ́run. Kì í ṣe sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Kò tdàgbà tó. Ọlọ́run kọ àwọn àwáwí wọ̀nyí pẹ̀lú òtítọ́ pé òun yóò di Jeremaih ní àmùrè, yóò spi fi agbára wọ̀ ọ́.

Mo wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní dásẹ̀ wọnú ìpè mi. Mo tiraka púpọ̀ níti ìwé, ọ̀pọ̀ olùkọ́ ló sì sọ fún mi pé n kò lè ṣe àṣeyọrí n;I ayé mi. Ṣùgbọ́n ní àárín ìrora àti ìtìjú yẹn, Ọlọ́n ní kí ń dìde kí n sì mú èrèdí tí òún fi dá mi ṣẹ. Àwọn ènìyàn ń pè mí ní ìkùnà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ kí hàn kedere pé n kò gbọdọ̀ pe ara mi ní ohun tí òun kò pè mí.

Nítorí náà, kín ni àwáwí rẹ? Ọlọ́run lè lò ọ́ láti kọ́ Ìjọba Rẹ̀ síbikíbi, kò ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí rẹ tàbí ìpele ìgbésí-ayé rẹ. Máṣe jẹ́ kí àwọn irọ́ sàtání ṣì ọ́ lọ́nà. Máṣe ro ara rẹ pín. Máṣe bu ara rẹ kù. Àti pé máṣe bu Ọlọ́run kù. Máṣe sọ fún ara rẹ pé o kò tíì dé ọja-orí tí ó yẹ fún lílò fún Ọlọ́run. Ó dára kí o tètè ṣe àwárí èrèdí Ọlọ́run fún ayé rẹ. kí o mọ̀ lónìí àti lọ́jọ́ gbogbo pé Ọlọ́run kì í pé àwọn ẹni tí ó kún ojú ìwọ̀n. Ó máa ń mú ẹni tí a pè kún ojú ìwọ̀n.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/