ÈRÈDÍ Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé JeremiahÀpẹrẹ
Èrèdí Ọlọ́run fún Ìṣẹ̀d
Ọlọ́run kì í ṣe olùkọ́ aláìlétò. Ó máa ń kọ́lé pẹ̀lú èrèdí ní ọkàn rẹ̀. Ẹsẹ bíbélì tòní fi hàn wá pé èrèdí wà fún ohun gbogbo lábẹ́ ọ̀run. Kò sọ pé èrèdí wà fún àwọn ohun kan, ṣùgbọ́n ó sọ pé èrèdí wà fún ohun gbogbo.
Bí èrèdí bá wà fún ohun gbogbo, a jẹ́ pé ó ní ètò fún ọ. Ọlọ́run kò gbìyànjú láti fi ọ́ ṣe rẹ́gí ohun tí Ó dá, ó dá ọ pẹ̀lú ìpnnu lọ́kàn. Ó pilẹ̀ ṣẹ̀dá rẹ fún èrèdí rẹ. kódà bí àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, ará tàbí ẹnikẹ́ni bá rò pé àṣìṣe ni ọ́, nínú ètò Ọlọ́run, ó jẹ́ kókó. Gbogbo ara rẹ̀, kódà àwọn èyí tí o lè má fẹ́ràn, ni a dá pẹ̀lú èrèdí kan. Ó ṣètò rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé wàá ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èrèdí ìṣẹ̀dá rẹ. ìdí nìyẹn tí ó fi ṣe pàtàkì láti rí ara rẹ bí Ọlọ́run ṣe rí ọ dípò bí ènìyàn ṣe rí ọ. Ìwòye ènìyàn kò ní jẹ́ kí o rí ara rẹ tán, ìwòye Ọlọ́run yóò jẹ́ kí o rí òkodoro àlàyé ara rẹ.
Nínú ìwé Gẹnẹsisi, a rí ìmọ̀ọ́mọ̀ Ọlọ́run ní ti dídá ènìyàn. Ọlọ́run nìkàn dá gbogbo ohun yòókù fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó fk dá ènìyàn, ó níláti sa ipá láti dá ènìyàn nípasẹ̀ pipe àwọn yòókù jọ, nítorí náà ló ṣe sọ pé… ‘ẹ’ jẹ́ kí, fi èyí wé àwọn ohun mìíràn tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan wọ̀nyí fúnrarẹ̀. Èyí nìkan ṣe àfihàn bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ọ́mọ̀ dá ènìyàn, ẹni tí í ṣe ‘‘Ìwọ’’. Nítorí náà, ó rọrùn láti sọ pé Olọ́run kò dá ènìyàn nítorí pé ó níláti dá ohun kan. Ó ṣe èyí fún èrèdí pàtàkì kan.
Nígbà tí ọ̀tá bá tọ̀ ọ́ wà pẹ̀lú gbólóhùn pé o jẹ́ àṣìṣe, gbọ̀n ọ́n dànù kí o sì pariwo sókè pé ÌWỌ KÌ Í ṢE ÀṢÌṢE wà á sí gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ èrò náà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo olùpèsè-ọjà ló ní èrèdí fún pípèsè ọjà kọ̀ọ̀kan. Ọlọrun dá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ètò àti ìlànà pàtàkì kan. Èrèdí ìgbélé-ayé ni kí á rí i dájú pé a gbé ìgbésí ayé wa láti jẹ́ kí èrèdí yìí wá sí ìmúṣẹ. Ẹkọ yìí dù láti wa àwàjinlẹ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/