ÌDARÍÀpẹrẹ
ÀYẸ̀WÒ ÌGBÉLÉWỌ̀N FÚN ÀWỌN OLÓRÍ
(Àwọn àmúyẹ tó fihàn pé Olórí kan kúnjú ìwọ̀n)
Olórí jẹ́ ẹni tí ó:
1. Ti jẹ́ Ọlọ́run ní 'bẹ́ẹ̀ ni'
Ìdarí ní í ṣe pẹ̀lú jíjọ̀wọ́ ohun gbogbo tí a jẹ́ tí a sì ní fún Olúwa. Ìfarajìn pátápátá fún ìfẹ́ Ẹni tí ó yanni sípò olórí ṣe pàtàkì gan-an, nítorí pé òun ni Ẹni tí ó ń darí ọ̀rọ̀ ayé ènìyàn (àti àwọn olórí àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn).
ó rọrùn láti tẹ̀lé ẹni tí ó ń tẹ̀lé Ọlọ́run.
"Ẹ máa ṣe àfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe àfarawé Kristi.’’ 1 Korinti 11:1.
2. Ní Ìdarí ara-ẹni tó dára
Àwòmọ́ pàtàkì kan fún olórí ni níní agbára láti ṣe àkóso ara-ẹni. Ó gbọ́dọ̀ lè tẹrí ẹran-ara rẹ̀ ba ‘lábẹ́’ ìfẹ́ Ọlọ́run kí ó sì gbé ara rẹ̀ ‘borí’ àwọn ìfẹ́ ẹran-ara. Ìṣàkóso ara-ẹni, ìkóra-ẹni-ní-ìjánu, ṣíṣe ohun tó tọ́ lásìkò tó tọ́, yíyọjú/wíwá sí ibi tó tọ́ láì náání ìrọ̀rùn… jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àmúyẹ ara ẹni fún olórí. Òwe 25:28, 1 Kor. 9:27.
3. Ní Ìmọ̀ọ́ṣe
Olórí gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ àwọn ẹni tí ó ń darí kí ó sì ní àtinúdá nípa títọ́ wọn sọ́nà àti dídarí wọn ní onírúurú ìgbà àti ìpele ìgbésí-ayé wọn.
Ìwé mímọ́ sọ nípa bí Ọba Dafidi ṣe ní ìmọ̀ọ́ṣe tó nínú dídarí àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
"Bẹ́ẹ̀ ni ó bọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà-títọ́ inú rẹ̀; ó sì fi ogbọ́n ọwọ́ rẹ̀ ṣe amọ̀nà wọn.’’ Orin Dafidi 78:72.
4. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníṣùúrù
Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn ẹni tí à ń darí wá láti àwọn ìpìlẹ̀ onírúurú, tí wọ́n sì ní onírúurú èrò àti ìrírí èyí tí ó lè nípa lórí bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń fèsì sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, nítorí náà olórí níláti ní ṣùúrù àti ìrẹ̀lẹ̀ nínú bíbá wọn ṣe.
gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùtàn ṣe gbọ́dọ̀ tutù ní dídarí àwọn àgùtàn tó wà ní ìsọ̀rí oríṣiríṣi (ọmọdé, àgbà, olóyún, abbl.), bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ó yẹ kí olórí jẹ́. Jesu gbé ìgbésí-ayé àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí olórí, tí ó ń ṣe àfihàn bí ó ṣe tutù, ní ṣùúrù àti ìrẹ̀lẹ̀ tó sí àwọn ẹni tí ó ń darí lojúkojú nígbà tí ó wà ní ayé.
Mt 11:29, Phil 2:3-4.
5. Ní ojú-àánú àti Ìfarajìn
Níní ìfẹ́ òtíta fún àwọn ẹni tí ó ń darí jẹ́ àmúyẹ pàtàkì fún olórí gidi. Mose ṣe àfihàn bí ó ṣe ní àánú sí àwọn ọmọ Israẹli nígbà tó dúró fún wọn níwájú Olúwa kí wọ́n má baà ṣègbé. Orin Dafidi 106:23, Mt 9:36.
6. Ń tọ́jú tí ó sì ń ṣìkẹ́ àwọn tí ó ń darí
Olórí gidi máa ń fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́jú nípa ti ẹ̀mí, ara, ìṣúná, àti ìwà. Ó ní ìtara sí àwọn àìní wọn, kò sì fi wọ́n sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣe aláìní. Ìṣe 20:28, Òwe 27:23.
7. Ń fi àpẹẹre ìdarí lélẹ̀
ọ̀nà kan tó múná dóko tí àwọn olórí fi máa ń kọ́ni àti darí ni láti di ohun tí wọ́n fẹ́ ki àwọn àtẹ̀lé wọn dì. Wọ́n máa ń ṣe àfihàn ìwà tí wọ́n ń retí lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ń darí. Nígbà tí iṣẹ́ kan bá yá, olórí ló máa ń bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ẹlòmìíràn. Johanu 13:13-15.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdarí jẹ́ ọ̀kan láti àwọn ìkànnì tí Ọlọ́run máa ń lò láti pèsè àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbésí-ayé àti iṣẹ̀-ńlá ti ìjọba rẹ̀. Àwọn èrèdí máa ń já gaara sí i, àwọn ìrìn-àjò máa dán mọ́nrán sí i láyé pẹ̀lú ìdarí tó tọ̀nà. Nítorí náà, Ọlọ́run ń mọ̀ọ́mọ̀ pe, ó sì ń fi agbára fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n máa mú ìpè ńlá yìí sẹ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/