Àṣẹ̀ṣẹ̀gbàgbọ́Àpẹrẹ
Òmìnira, ìtúsílẹ̀ àti ìdásílẹ̀!
Ẹ̀bùn ìgbàlà jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ tó wá pẹ̀lú iye, ẹ̀mí omo Ọlọ́run. Ó ná Ọlọ́run ní ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ láti san gbèsè tí kò jẹ. Dípò ìdálẹ́bi,ó ṣe pàtàkì pé kí ó rí ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run fún ọ àti bí k'O ṣe ní fa ohun rere kankan sẹ́yìn lọ́dọ̀ rẹ.
Ẹni tí a ti gbàlà gbọ́dọ̀ gbé pẹ̀lú ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ òmìnira àti ìtúsílẹ̀. O kìí ṣe ẹni tí o jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí. Bí ẹnikẹ́ni bá wà nínú Krístì, ó di ẹ̀dá titun, ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, ohun gbogbo sì di tuntun. Bí Bíbélì ṣe júwe ẹni tí o ti gba Jésù Krístì. Ó tún wí pé kò sí ìdálẹ́bi fún àwọn tó jẹ́ ti Jésù Krístì.
Ìwọ̀n ìdáríjì tí Ọlọ́run fún ọ kò dá lórí bí ó ṣe rò pé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ 'wúwo' tàbí 'fúyẹ́'. Ó ti mú ẹsẹ rẹ kúrò bí ìlà òorùn ṣe jìnnà sí ìwọ̀ òórùn.
A kò dá ọ mọ̀ pẹ̀lú àwọn ìpinnu tí kò yẹ tí o ti ṣe sẹ́yìn. Faramọ́ ẹni tí o jẹ́ nínú Krístì báyìí.
Nípa Ìpèsè yìí
Jésù Krístì wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àtúnbí sínú ayé tuntun ni. Nítorí náà ó ṣe pàtàkì pé kí onígbàgbọ́ tuntun ní òye ìhùwàsí, àǹfààní àti àṣà ayé tuntun yìí.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/