OGUN LÓRÍ IBẸ̀RÙÀpẹrẹ

OGUN LÓRÍ IBẸ̀RÙ

Ọjọ́ 3 nínú 3

OGUN LÓRÍ IBẸ̀RÙ (APA KẸTA)

ÌṢẸ́GUN LÓRÍ IBẸ̀RÙ

2 Tímótì 1:6–7

“Nítorí náà ni mo ṣe ń rán ọ létí pé kí o mú ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ó wà nínú rẹ jó, èyí tí o gba nípasẹ̀ fífi ọwọ́ mi lé e lórí.

Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ibẹ̀rù, ṣùgbọ́n ti agbára, àti ìfẹ́, àti ọgbọ́n inú tí ó dáa.”

Ẹ̀KỌ́

Ibẹ̀rù kì í ti odo Ọlọ́run wá

• Kò sí nínú ohun tí Ọlọ́run fi sínú wa.

• Ó jẹ́ ohun tó ń fa ìdènà sí ìgbésí-ayé ọmọ Ọlọ́run.

Bí a ṣe lè borí ibẹ̀rù

1• Mú ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ó wà nínú rẹ jó.

2• Kọ orin ẹ̀mí

3• Gbàdúrà

4• Lo àkókò dáadáa láti ronú jinlẹ̀ lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

• Nígbà tí o bá ṣe èyí, ìmòye ẹni tí o jẹ nínú Kristi yóò jí, ibẹ̀rù yóò sì sá lọ.

Ìmúlò ìmọ̀ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run se Pataki gidigidi.

• Rántí pé a ni awon ẹ̀to gege bibi ọmọ olorun.

Mase gbagbe pe olọ́run ni Baba wa, kò sí ohun tó tóbi ju olorun lọ.

Nitorina Ẹ̀mí ibẹ̀rù kò lè ṣàṣeyọrí lórí wa mọ́

Ìpari:

Ibẹ̀rù kì í gbọ́dọ̀ ní àyè nínú ìgbésí-ayé ọmọ Ọlọ́run.

Nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ọlọ́run, igboya àti ìmọ̀ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, a lè jagun ki a si bori ibẹ̀rù, ti a o fi le gbe ìgbé-ayé pípé nínú Kristi.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

OGUN LÓRÍ IBẸ̀RÙ

Ogun Lórí Ibẹ̀rù jẹ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀mí tó kọ́ wa pé ibẹ̀rù kì í ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ó ṣàlàyé orísun àti irú ibẹ̀rù, ó sì ń dari ọmọ Ọlọ́run sí bí a ṣe lè borí rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹni tí a jẹ́ nínú Kristi, igboya, àti ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Olufemi Ezekiel Adebayo fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.femiadebayo.org

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ