1
AISAYA 25:1
Yoruba Bible
OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi. N óo gbé ọ ga: n óo yin orúkọ rẹ. Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu, o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́, o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 25:1
2
AISAYA 25:8
Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 25:8
3
AISAYA 25:9
Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”
Ṣàwárí AISAYA 25:9
4
AISAYA 25:7
Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 25:7
5
AISAYA 25:6
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára.
Ṣàwárí AISAYA 25:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò